Olorun yio si nu omije gbogbo nu kuro li oju won; ki yio si si iku mo, tabi ofo, tabi ekun, beni ki yio si irora mo; nitoripe ohun atijo ti koja lo. Eniti o joko lori ite ni si wipe, Kiyesi i, mo so ohun gbogbo di otun. O si wi fun mi pe,Kowe re: nitori oro wonyi ododo ati otito ni nwon. O si wi fun mi pe, O pari. Emi ni Alfa ati Omega,ipilese ati opin. Emi o si fi omi fun eniti ongbe ngbe lati orisun omi iye lofe.